Yunifásítì Howard (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì: Howard University tàbí Howard tàbí HU) ni yunifásítì aládáni, tó ní ìwé áṣẹ látọwọ́ ìjọba àpapọ̀ tó bùdó sí Washington, D.C. ní Amẹ́ríkà. Yunifásítì Howard jẹ́ ìkan nínú àwọn yunifásítì tí wọ́n dásílẹ̀ fún àwọn aláwọ̀dúdú (HBCU) ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n dá Yunifásítì Howard sílẹ̀ ní 1867.