Adunni Ade
òṣèré orí ìtàgé ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Adunni Ade (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún 1976) jẹ́ òṣèré àti aláwòṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]Adunni Ade jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèré amóhùn-máwòrán ní ere orí ìtàgé tí Yorùbá.
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ àti ẹ̀kọ́
A bí Adunni ní agbèègbè ti Ayaba, ìlú Niu Yoki (Queens, New York), ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìyá rẹ wá láti orílẹ̀-èdè Jẹmani(Germany), bàbá rẹ sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yoruba láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó àti Amẹ́ríkà ni wọ́n ti tọ́ Adunni dàgbà. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ipinle Eko àti ní Ipinle Ogun. Bàbá rẹ tí ó jẹ́ oníṣòwò pàtàkì tí ó sì fi Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ibùgbé ṣe àtìlẹyìn fun un láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣirò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Kenturky ní ọdún 2008.
Remove ads
Iṣẹ́ tí ó yàn laayo
Adunni ṣe iṣẹ́ ní ẹ̀ka ilé gbígbé àti ìṣédúró ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí ó tó di wípé ó yẹ̀bá lọ sí ilé iṣẹ́ ìdánilárayá. Adunni dáwọ́lé iṣẹ́ àṣà àti àwòṣe èyí tí ó mú un fi ara hàn nínú "America's Next Top Model". Nígbàtí ó padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó kó ipa àkọ́kọ́ pẹ̀lú àwọn òṣèré Nollywood nínú fiimu èdè Yoruba tí àkòrí rẹ jẹ́ "ìwọ tàbí Èmi" ní ọdún 2013. Adunni tún ti kópa nínú àwọn sinimá oríṣiríṣi ní ède Yoruba àti ní ède Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú àwọn orin fídíò fún Sound Sultan àti Ice Prince.[3][4] Ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Stella láti ọwọ́ Nigerian Institute of Journalism fún akitiyan rẹ̀ lórí i gbígbé àṣà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga.[5] Ní ọdún 2017, ó di aṣojú ìyàsọ́tọ̀ fún OUD Majestic.[6]
Remove ads
Ìgbésí ayé rẹ
Adunni bí ọmọ ọkùrin méjì. Orúkọ wọn ni D'Marion àti Ayden. Ó sọ wípé lẹ́yìn tí òun ti ṣe ìpinnu tí ó nira láti yà pẹ̀lú bàbá wọn, òun yí ò tẹ̀síwájú láti jẹ́ òbí ànìkànjọ̀kan.[7][8][9]
Filmography rẹ tí a yàn
Fiimu
- Iwo tabi emi (You or I) (2013)[10][11]
- What's Within (2014)
- 2nd Honeymoon (2014)
- Head Gone (2015)
- So in Love. (2015)
- Schemers (2016)
- Diary of a Lagos Girl (2016)
- Diary of a Lagos girl (2016)
- For The Wrong Reasons (2016)
- It's Her Day (2016) Earned her the nomination for Best Supporting Actress in Africa's biggest Movie Awards, AMVCA in 2017. She also won Best Supporting Actress Award at the Lagos Film Festival for the movie.
- The Blogger's Wife (2017)
- Guyn Man (2017)
- Boss of All Bosses (2018)
- The Vendor (2018)
- House Of Contention (2019)
Tẹlifisiọnu
- Behind the Cloud
- Babatunde Diaries
- Jenifa's Diary Season 2
- Sons of the caliphate Season 2
Remove ads
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads