Samuel Ortom
Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Samuel Ioraer Ortom tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 1961 (23rd April 1961) jẹ́ òṣèlú, oníṣòwò àti aláàánú ọlọ́rẹ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Benue lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue kí ó tó di ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ́n oṣù karùn-ún ọdún 2023, tí àlùfáà ìjọ Kátólíìkì Hyacinth Iormem Alia dípò rẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò gbogboògbò ọdún 2023. Lọ́dún 2015 ló wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, nígbà tó di ọdún 2019, ó tún wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Benue fún sáà kejì ṣùgbọ́n lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP. Nígbà ìṣèjọba Ààrẹ ana, Goodluck Jonathan, Samuel Ortom ni Mínísítà abẹ́lé fún karai àti dídá Okowò sílẹ̀.
Remove ads
Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a t sọ ṣáájú, wọn bí Samuel Ortom lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 1961 (23rd April 1961) ní ìjọba ìbílẹ̀ Guma ní ìpínlẹ̀ Benue , lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ni St. John's Primary School, ní ìlú Gboko lọ́dún 1970, àti St. Catherine's Primary School, ní ìlú Makurdi, olú ìlú ìpínlẹ̀ Benue lọ́dún 1974, ó parí ẹ̀kọ́ àkóbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1976. Ortom tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Idah Secondary Commercial College, Idah ní ìpínlẹ̀ Kogí, ṣùgbọ́n kò parí rẹ̀ nítorí àìsówó lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. Ní àkókò yìí ló di awakọ̀ èrò jẹun. [1] He became a professional driver.[3]. Samuel Ortom kò jẹ́ kí èyí fà á sẹ́yìn, nígbà tí ó lówó, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ títí ó fi gba ìwé ẹ̀rí ọ̀mọ̀wé, Doctor of Philosophy (Ph.D) ní Commonwealth University, Belize, nípa ètò gbélé-kàwé.[4] Ṣíwájú àkókò yìí, ó kàwé gboyè Dípólómà nínú ìmọ̀ ọjà títà ni Ahmadu Bello University, ní ìlú Zaria àti ní Benu State University, níbi tí ó ti kàwé gboyè Dípólómà nínú iṣẹ́ ìròyìn lọ́dún 1998.
Remove ads
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads