Chigul
Òṣéré orí ìtàgé From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Chioma Omeruah, tí a mọ̀ orúkọ ìnagi rẹ̀ sí Chigul, jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, akọrin, àti òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ipa apanilẹ́rìn-ín rẹ̀ tí ó maá n sábà ṣe ní gbogbo ìgbá
Remove ads
Ìsẹ̀mí rẹ̀
Wọ́n bí Omeruah sí ìlú Èkó. Òun ni àbílé kejì nínu àwọn ọmọ mẹ́rin ti àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Samson Omeruah.[1]
Ó lọ sí ilé-ìwé girama méjì kan ní ìlú Jọs àti ní ìlú ìkẹjà,[2] ó sì tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Ábíá fún oṣù mẹ́ta, sááju kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ̀ gíga Delaware State University níbití ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nípa òfin tó de àwọn ìwà òdaràn.[3][4] Nítorí àìṣedédé rẹ̀ nínu ẹ̀kọ́ náà, ó padà tún kẹ́kọ̀ọ́ èdè Faransé láti ilé-ìwé Delaware State University bákan náà. Ó padà sí Nàìjíríà lẹ́hìn tí ó ti lo ọdún méjìlá ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà[5]
Ó kọ́kọ́ di akọrin lábẹ orúkọ C-Flow ṣùgbọ́n orúkọ Chigul bo ti tẹ́lẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́hìn kíkó àwọn ipa apanilẹ́rìn-ín rẹ̀ nínu àwọn eré. Àkọ́lé àkọ́kọ́ orin rẹ̀ tí ó kọ ni "Kilode", èyí tí ó ṣe pẹ̀lú gbígbohùn rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì pín fún àwọn òrẹ́ rẹ̀.[6] Ó tí kópa nínu eré Nollywood kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Road to Yesterday.[7]
Remove ads
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
- Road to Yesterday (2015)
- The Wedding Party 2 (2017)
- Banana Island Ghost (2017)[8]
- Chief Daddy (2018)
- The Ghost and the Tout (2018)
- Charge and Bail (2021)
Àwọn amì-ẹ̀yẹ àti ìfisọ́rí rẹ̀
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads