David Ejoor
Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
David Akpode Ejoor RCDS, PSC, (10 January 1932 – 10 February 2019) jé̩ o̩mo̩ orílè̩-èdè Nàìjíríà,ó jẹ́ olórí Agbègbè àárín-Apá ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà té̩lè̩ kí ó tó di Ìpínlè̩ Bendel 1976. Ejoor tún jé̩ ọ̀gá àwọn ọmọọṣẹ́ Jagunjagun Orí-ilẹ̀ Nàìjíríà (COAS) láti ọdún 1971 di 1975.
Remove ads
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ Ejoor, ó darí àwọn ẹ̀ṣọ́ níbi ayẹyẹ ìgbé-àsíá sóké ní òru ọjọ́ ìgbòmìnira.[2] Ejoor sọ ọ́ di mímọ̀ pé Lieutenant Colonel ìgbà náà, tí í ṣeChukwuemeka Odumegwu Ojukwu àti Ológun Yakubu Gowon wá bá òun láti sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n á ṣe gbìmọ̀ dìtẹ̀ lásìkò ètò ìdìbò ti ọdún 1964.[3]
[4] Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní, púpọ̀ nínú àwọn òṣìṣẹ́ yìí lọ sí patí láti lọ ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú Brigadier Zakariya Maimalari tó ń ṣe ìgbéyàwó.[5] Lẹ́yìn náà, Ejoor padà sí ilé-ìgbafẹ́ tó wà ní Ikoyi. Ó jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, pẹ̀lú òkú ẹni tí wọ́n jọ sùn sínú yàrá kan náà, ìyẹn Lieutenant-Colonel Abogo Largema, nínú ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀, èyí tí Emmanuel Ifeajuna àti Godfrey Ezedigbo pa ní alẹ́ ọjọ́ náá.[6]
Remove ads
Ayé rẹ̀ àti ikú rẹ̀
Wọ́n bí Ejoor ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní ọdún 1932 sínú ìdílé àwọn ará Urhobo ní Ovu.
Ejoor kú ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kejì ọdún 2019.[7] Ó kú nígbà tó wà ní ọmọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún.
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads