David Mark

Olóṣèlú Naijiria From Wikipedia, the free encyclopedia

David Mark
Remove ads

David Alechenu Bonaventure Mark (bíi ní Oṣù kẹrin Ọdún 1948) jẹ́ ológun tí ó ti fẹ̀hìntì àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n dìbò yàn wọlé gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ìpínlẹ̀ Benue ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó jẹ́ aṣojú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lẹ́yìn tí ó wọlé látàrí ètò ìdìbò ti oṣù kẹrin ọdún 2007 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party.[2] Ó jẹ́ ààrẹ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.[3][4]

Quick Facts Ààrẹ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti ilẹ̀ Nàìjíríà, Deputy ...
Remove ads

Ìgbé ayé àti Èkó rè

A bí Mark si ìlú Otukpo ní ìpínlè Benue ni osù kerin odun 1948. O lo si ilé-ìwé St. Francis Catholic Practicing ko to look since ilé-ìwé àwon ologun. Léyìn náà, o tun lo kàwé ni Nigeria Defense Academy.[3] Wón so di 2nd Lieutenant ni odun 1970, wo si tun so di Captaini ni odun 1971, ótún padà di alaga Abandoned Properties implementation Committee ni iwo ilà oòrùn ni odun 1976.

Minisita

Mark jé olori Ministry of Communication àti àwon èka rè: Nigerian Telecommunications Limited(NITEL) àti Nigerian Postal Service(NIPOST).

Aare ìgbìmò asofin agba ti Nàìjirià

A yan Mark gégé bi ààré ilé ìgbìmò asofin àgbà ti Naijiria ní ojó kefa, osu Kefa odun 2007. [5]

David tún díje fun Senato agbègbè Benue South lekan si ni osu kerin odun 2011, a si yan fun isejoba kerin.[6] David so pe idibo àwon eniyan ni o gbé depo, o si so fún àwon olutako rè láti sisé papò láti tún Nàìjíríà se.[4]

Nígbà ti àwon ilé ìgbìmò asofin un tún òfin Nàìjíríà se, Mark so fun àwon Senato tó kù rè láti fi àwon omo Nàìjirià si wajú ara won.[7]

Léyìn ìgbà ti àwon orílè-èdè United Kingdom satako si Nàìjirià, won si so pé wón ma se idaduro si àwon iranlowo ti wón un fun Nàìjirià. Mark so pe ki wón fi iranlowo won pa mó.[8]

Ni osu kesan odun 2018, Mark ni ipinu láti díje fun ipò ááre orílè-èdè Nàìjirià, o si yan Zainab Abdulkadir Kure ati Abba Ejemni si egbe ti o ma sé idari ipolongo ìdíje rè.[9]

Ìgbé ayé rè

O feran eré idaraya golf, tennis àti Squash.[10] O je Christieni, èyà Idoma sì ni èyà rè. O ni ìyàwó merin sí marun.>[11]

Mark ni ilé àti Helicopter ati ìbi ibalesi fún Helicopter. .[12]

Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads