Ìpínlẹ̀ Edo
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Edo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó wà ní agbègbè ẹkù gúúsù ti orílẹ̀ èdè náà.[1] Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ètò-ìkànìyàn lórílẹ̀ èdè ti ọdún 2006, ìpínlẹ̀ náà jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́ta-àbọ̀-dínní-díẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[2] Ìpínlẹ̀ Edo jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè gẹ́gẹ́ bí títóbi ilẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[3] Olu-ilu ìpínlẹ̀ náà àti ìlú rè, ni Ìlu Benin, tí ó jẹ́ ìlú ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rin tí ó tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó sì jẹ́ ibùdó ilé-iṣẹ́ tí ń ṣe rọ́bà orílẹ̀ èdèy.[4][5] Wọ́n dáa sílẹ̀ ní ọdún 1991 látara Ìpínlẹ̀ Bendel tẹ́lẹ̀rí, wọ́n sì tún mọ̀ọ́ sí ìró ọkàn orílẹ̀ èdè.[6] Ìpínlẹ̀ Edo pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Anambra sí ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Delta sí gúúsù-ìlà-oòrùn àti gúúsù-gúúsù àti pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ondo sí ìwọ̀-oòrùn.[7]
Ìpínlẹ̀ Edo State nickname: Heart Beat of Nigeria | ||
Location | ||
---|---|---|
![]() | ||
Statistics | ||
Governor (List) |
Adams Oshiomhole (AC) | |
Date Created | 27 August 1991 | |
Capital | Benin City | |
Area | 17,802 km² Ranked 22nd | |
Population 1991 Census 2005 estimate |
Ranked 27th 2,159,848 3,497,502 | |
ISO 3166-2 | NG-ED |

Àwọn ààlà òde-òní ti Ìpínlẹ̀ Edo yí àwọn agbègbè tí wọ́n jẹ́ agbègbè oríṣiríṣi ìjọba àti ìjọba tí wọ́n dásílẹ̀ ní ọgọ́rùn ọdún mọ́kànlá AD sẹyìn ká, ìyẹn Ìjọba Benin.[8] Ìlú àtijọ́ ti Edo, agbègbè ti ìlu Benin òde-òní, jẹ́ ilé sí díẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́-orílẹ̀ tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé.[9] Ní ọdún 1897, ìjọba aláwọ̀-funfun ṣe ìrìn-àjò ìjìyà ti agbègbè kan, tí ó pa púpọ̀ nínú àwọn ìlú Edo àtijọ́ run àti ṣíṣàfikún agbègbè náà sínú ohun tí yóò di gúúsù Nàìjíríà lábẹ́ àbò ìjọba aláwọ̀-funfun.[10][11]
Ìpínlẹ̀ Edo jẹ́ ìpínlẹ̀ tí ó kúnfún àwọn oríṣiríṣi àwọn olùgbé tí ó gbilẹ̀ jẹ́ àwọn ará Edoid, pẹ̀lú àwọn ará Edo (or Bini),[12] Esan, Owan àti Afemai people.[13] ÈdèEdoid tí ó wọ́pọ̀ ní sísọ jùlọ ni èdè Edo, ní èyí tí wọ́n máa ń sọ jù ní ìlu Benin.[14] Ẹ̀sin kììtẹ́nì ni ó gbilẹ̀ jù ní Ìpínlẹ̀ Edo. Àwọn arìnrìnàjò onígbàgbọ́ Portuguese ni wọ́n mu wa si agbègbè náà ni gbèdéke ọgọ́rùn ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Wọ́n ṣe ẹ̀sin Mùsùlùmí àti ẹ̀sìn àbáláyé náà.[15]
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lábẹ́ rẹ
Àwọn ìjọba ìbị́lẹ̀ méjìdínlógun ló wà lábẹ́ ìpínlẹ̀ Edo.
- Akoko-Edo
- Egor
- Esan Central
- Esan North-East
- Esan South-East
- Esan West
- Etsako Central
- Etsako East
- Etsako West
- Igueben
- Ikpoba-Okha
- Oredo
- Orhionmwon
- Ovia North-East
- Ovia South-West
- Owan East
- Owan West
- Uhunmwonde
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.