Ìpínlẹ̀ Òndó

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Ìpínlẹ̀ Òndómap
Remove ads

Ìpínlẹ̀ Ondo jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù-ìwọ̀oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. wọ́n da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejí ọdún 1976 látara àwọn Ìpínlẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn tẹ́lẹ̀ rí.[4] Ìpínlẹ̀ Ondo pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ekitiàríwá, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Edo sí ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Delta sí gúúsù-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ogun sí gúúsù-ìwọ̀ oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Osun sí àríwá-ìwọ̀ oòrùn, àti pẹ̀lú Atlantic Ocean sí gúúsù.[5] Tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Akure, ìyẹn olú-ìlu ẹkùn-ìjọba Akure àtijọ.[6] Ìpínlẹ̀ Ondo ni igbó mangrove-swamp wà lẹ́ba àwọn ìgbèríko ìlu Benin.[7]

Thumb
Creek in southern Ondo state
More information Location, Statistics ...
Ìtàn ṣókí nípa Ondon láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Ondo.
Quick facts Ondo, Country ...

Tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ njẹ́ "Sunshine State", Ìpínlẹ̀ Ondo jé ọ̀kàndìnlógún Ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,[8] tí ó sì jẹ́ ìpínlẹ̀ karùndínlọ́gbọ̀n tó fẹ̀ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ilẹ̀ gbígbà.[9] Yorubani ó gbilẹ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà,[10][11] èdè Yorùbá ni wọn ń sọ jù níbẹ̀.[12] Ilé-iṣẹ́ epo-bẹntiróò ni ó gbilẹ̀ jù gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé ní ìpínlẹ̀ náà. òwo Cocoa, wíwa asphalt, àti àwọn ọ̀gọ̀rọ̀ iṣẹ́ etí òkun pẹ̀lú èto ọrọ̀-ajé ìpínlẹ̀ náà.[13] Ilé àwọn òkè Idanre ni, tí ó kó ipa tó ga jùlọ nínú ìdajì àwọn agbègbè ìwọ̀-oòrùn tí ó làmìlaka lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó ga ju ìwọn ọgọ́run mítà lọ ní títayọ.

Remove ads

Ìjọba àti àwùjọ

Ìpínlẹ̀ náà ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, àwọn tí ó jẹ́ gbòógì náà nìwọ̀nyí Akoko, Akure, Okitipupa, Ondo, Ilaje, Idanre àti Owo. Púpọ̀ nínú àwọn ará ìpínlẹ̀ náà ń gbé ní àwọn ilu tí ó lajú. Àwọn fáfitì ìjọba tí ó gbajúgbajà ní ìpínlẹ̀ Ondonáà nìwọ̀nyí Federal University of Technology Akure, Akure Ondo State University of Science and Technology, Okitipupa University of Medical Sciences, Ondo, Ondo àti Adekunle Ajasin University, Akungba Akoko.[14]

Remove ads

Itan ti ipinle Ondo

Ipinle Ondo, oorun Nigeria. A ti ṣẹda rẹ lati agbegbe Ondo tẹlẹ ti ipinlẹ Iwọ-oorun tẹlẹ ni ọdun 1976. Awọn ipinlẹ Kwara ati Kogi ni ariwa, Edo ni ila-oorun, Delta ni guusu ila-oorun, ati Osun ati Ogun ni iwọ-oorun ati lẹba Bight of Benin ti Okun Atlantic ni guusu. Ipinle Ondo ni igbo mangrove-swamp ti o wa nitosi Bight of Benin, igbo ojo otutu ni aarin aarin, ati savanna ti o ni igi ni awọn oke pẹlẹbẹ ti awọn Oke Yoruba ni ariwa.[15]

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, àwọn ọjà olóyè sì ni òwú àti taba láti àríwá, cacao láti àárín gbùngbùn, àti rọba àti igi (teak àti igi líle) láti gúúsù àti ìlà oòrùn; epo ọpẹ ati awọn kernels ni a gbin fun okeere jakejado ipinle. Ondo ni orile-ede Naijiria ti o nse koko koko. Awọn irugbin miiran pẹlu iresi, iṣu, agbado (agbado), kofi, taro, cassava (manioc), ẹfọ, ati awọn eso. Awọn ile-iṣẹ ibilẹ pẹlu ṣiṣe apadì o, iṣẹṣọ asọ, iṣẹṣọ, iṣẹgbẹnà, ati alagbẹdẹ. Awọn ohun idogo erupẹ pẹlu kaolin, pyrites, irin irin, epo, ati edu. Ile-iṣọ aṣọ kan wa ni Ado-Ekiti ati ile-iṣẹ iṣelọpọ epo-ọpẹ ni Okitipupa.[15]

Ìpínlẹ̀ náà, tí àwọn Yorùbá ń gbé ní pàtàkì, àwọn ènìyàn tí ó ní àṣà gbígbé ní àwọn ìlú, ní ìpín púpọ̀ nínú àwọn olùgbé ìlú. Akure, olu-ilu ipinle, nyara ni idagbasoke si ile-iṣẹ iṣowo ati ile-iṣẹ ati pe o jẹ aaye ti ile-ẹkọ giga ti imọ-ẹrọ ti apapo. Orisun omi gbigbona Ikogosi ati awọn oke Idanre itan jẹ awọn aaye ti iwulo. Opopona nla lati Ilu Benin si Eko kọja ni apa gusu ti ipinlẹ naa. Agbegbe 5,639 square miles (14,606 square km). Agbejade. (2006) 3.441.024.[15]

Àwọn ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀

Ìpínlẹ̀ Ondo ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, wọn sì ni:

  • Akoko North-East (headquarters in Ikare)
  • Akoko North-West (headquarters in Okeagbe)
  • Akoko South-East (headquarters in Isua)
  • Akoko South-West (headquarters in Oka)
  • Akure North (headquarters in Iju / Itaogbolu)
  • Akure South (headquarters in Akure)
  • Ese Odo (headquarters in Igbekebo)
  • Idanre (headquarters in Owena)
  • Ifedore (headquarters in Igbara Oke)
  • Ilaje (headquarters in Igbokoda)
  • Ile Oluji/Okeigbo (headquarters in Ile Oluji)
  • Irele (headquarters Ode-Irele)
  • Odigbo (headquarters in Ore)
  • Okitipupa (headquarters in Okitipupa)
  • Ondo East (headquarters in Bolorunduro)
  • Ondo West (headquarters Ondo Town[16])
  • Ose (headquarters in Ifon)
  • Owo (headquarters in Owo Town)
Remove ads

Gómìnà

Akeredolu Oluwarotimi Odunayo[17] jẹ́ gómìnà lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Ìpínlẹ̀ Ondo.[18] Gómìnà Oluwarotimi Odunayo Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu "All Progressives Congress" (APC) ni wọ́n ṣe ìbúra fún bọ́sípò ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejì, ọdún 2017 jẹ lẹ́yìn Olusegun Mimiko.[19] Lucky Aiyedatiwa ni igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo.[20]

Àwọn ọ̀wọ́ ẹ̀yà

Ọ̀wọ́ ẹ̀yà ní ìpínlẹ̀ Ondo kún fún ọ̀pọ̀ ẹ̀yà Yoruba ìdá ọ̀wọ́ ti Idanre, Akoko, Akure, Ikale, Ilaje, Ondo, àti àwọn èèyàn Owo. Ará Ijaw, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn Apoi àti Arogbo ń gbé ní gúúsù-ìlà-oòrùn létí omi tó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Edo. Díẹ̀ nínú àwọn èrò tí wọ́n ń sọ ẹ̀ka èdè Yorùbá tí ó jọ èdè IfeOke-Igbo tí ó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Osun.[21] Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èrò yìí jẹ́ ẹlẹ́siǹ Kììtẹ́nì; tí àwọn diẹ jẹ́ ẹlẹ́siǹ Mùsùlùmí àti àbàlàyé.[22][23]

Remove ads

Àwọn èdè

Àtòpọ̀ àwọn èdè ní ìpínlẹ̀ Ondo látọwọ́ àwọn ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀:[24]

More information LGA, Languages ...
Remove ads

Àwọn ohun àlùmọ́nì ní ìpínlẹ̀ Ondo

Àwọn ohun wọ̀nyí ni ohun àlùmọ́nì ti wọ́n ní ìpínlẹ̀ Ondo:[25]

  • Bitumen
  • Coal
  • Dimension stones
  • Feldspar
  • Gemstones
  • Glass/and
  • Granite
  • Gypsum
  • Kaolin
  • Limestone & oil/gas

Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga

Remove ads

Àtẹ́ dẹ̀mógíráfì

More information Local government area, Male ...
Remove ads

Àwọn èèyàn Jànkànjànkàn

Àwọn Ilé-iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti amóhùn-máwòrán ní ìpínlẹ̀ Ondo

Àwọn àwòrán

References

Àwọn ìtàkùn-ìtọ́kasí

Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads