Enyinna Nwigwe
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Enyinna Nwigwe jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ati olùgbéré-jáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó gbé àwọn aládùn bíi: The Wedding Party, Black November, àti Black Gold jáde.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀
Wọ́n tó Nwigwe ní ìlú Ngor Okpala ní Ìpínlẹ̀ Imo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ fásìtì ti ìlú Calabar ní Ìpínlẹ̀ Delta nínú ìmọ̀ Ìṣúná. [2]
Iṣẹ́ rẹ̀
Nwigwe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lásìkò tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ módẹ́ẹ̀lì pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ runway àti print model ṣáájú kí ó tó darapọ̀ mó iṣẹ́ tíátà.[3] Ó gbé eré kan jáde tí ó pè ní Wheel of Change eré tí Jeta Amata darí rẹ̀ ní ọdún 2004. [4]Ní báyìí, Nwigwe ń lọ sí ìlú Los Angeles ati orílẹ̀-èdè Nigeria láti ṣíṣe rẹ̀. [5] Ó ti kópa nínú àwọn eré orísiríṣi ṣáájú kí ó tó kópa nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Black November tí àwọn òṣèré bíi Kim Basinger, Mickey Rourke, Vivica A. Fox, Akon, Wyclef Jean, and Anne Heche ti kópa ní ọdún.[6] Ó kópa bí olú-èdá ìtàn gẹ́gẹ́ bí páítọ̀ nínú eré Hell or High Water, ní ọdún 2015. Lẹ́yìn eré yí ni ó pinu láti máa kòpa nínú eré tí ó bá ti níṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.[7][8] Ní ọdún 2017, News of Africa pèé ní Ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn méjìlá tí ojú wọn fani-mọ́ra jùlọ ní Nollywood, lọ́dún náà. [9]
Àwọn eré rẹ̀
Àwọn eré orì amóhù-máwòrán
Remove ads
Àwọn amì-ẹ̀yẹ ati ìfisọrí rẹ̀
Wọ́n yan Nwigwe amì-ẹ̀yẹ ti Nollywood and African Film Critics Award, ní ọdún 2015, ati òṣèré amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó peregedé jùlọ níbi ayẹyẹ African Oscars nínú eré Black November.[11] Ní ọdún 2016, wọ́n tún yàn án fún amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó peregedé jùlọ nínú eré Gẹ̀ẹ́sì níbi amì-ẹ̀yẹ City People Entertainment Awards.[12]
Àwọn Ìtàkùn ìjásóde
- Àdàkọ:Imdbname
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads