Ira Aldridge
Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Ira Frederick Aldridge (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1807, tí ó sì di olóògbé ní ọjọ́ keje oṣù kejọ, ọdún1867) jẹ́ òṣèrékùnrin àti adarí eré orí-ìtàgé tó wá láti orílẹ̀-èdè American. Ó di ìlú-mọ̀ọ́-ká látàrí fífi ẹ̀dá-ìtàn Shakespeate hàn. James Hewlett àti Aldridge ni a lè pè ní àwọn aláwọ̀-dúdú àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń ṣe eré apanilẹ́kún.
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti iṣẹ́ rẹ̀


Ìlú New York City ní wọ́n bí Aldridge sí, sínú ìdílé ìránṣẹ́ Ọlọ́run Daniel àti Luranah, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1807. Àmọ́ àwọn ìwé kan sọ pé wọ́n bi sí Bel Air, Maryland.[1]
Iṣẹ́ Aldridge àkọ́kọ́ wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún 1820 pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Afirika kan, èyí tí William Henry Brown àti James Hewlett ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.[2][3]
Ní oṣù karùn-ún, ọdún 1825, nígbà tí ó pé ọmọdún mẹ́tàdínlógún, Aldridge ṣe ìfarahàn àkọ́kọ́ rẹ̀ sí ìlú London lásìkò tí wọ́n fẹ́ ṣe àgbéjáde fíìmùOthello.[4] Ní oṣù kẹwàá ọdún 1825 bákan náà, Aldridge tún ṣiṣẹ́ gọbọi mìíràn ní London Royal Coburg Theatre, ó sì di aláwọ̀-dúdú àkọ́kọ́ tí á ṣe ìdásílẹ̀ ara rẹ̀ ní ilẹ̀ àjèjì. Ó ṣe Oroonoko nínú fíìmù The Revolt of Surinam, or A Slave's Revenge.[3]


Remove ads
Ìdílé Aldridge
- Ira Daniel Aldridge, 1847–?. olùkọ́. Ó ṣí lọ sí Australia ní ọdún1867.[5]
- Irene Luranah Pauline Aldridge, 1860–1932. olórin opera.[4]
- Ira Frederick Olaff Aldridge, 1862–1886. Olórin àti akọ-orin-kalẹ̀.[6]
- Amanda Christina Elizabeth Aldridge (Amanda Ira Aldridge), 1866–1956. olórin opera, òǹkọ̀wé àti a-ṣẹ̀dá-orin lábẹ́ Montague Ring.[7]
- Rachael Margaret Frederika Aldridge, b.1868;[8] ó kú ní ìgbà èwe rẹ̀ ní ọdún 1869.[9]
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads