Mayorkun
From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Adewale Mayowa Emmanuel (wọ́n bi ní 23 Oṣù Kẹta, ọdún1994), wọ́n mọ̀ ọ́ sí MayorKun, tí í ṣe orúkọ iṣẹ́ àti orúkọ ìnagijẹ rẹ̀. Ó jẹ́ olórin àti akọrin tí ó máa ń kọ orin tí ó wá láti orílẹ́-èdè Nàìjíríà, .[1] Ó kọ orin àṣehàn fún orin Davido' kan tí í ṣe "The Money"ní orí ẹ̀rọ Twitter níbi tí Davido ti rí iṣẹ́ ẹ̀bùn orin kíkọ ẹ̀.[2] Mayorkun ki ọwọ́ bọ̀wé láti di olórin ní abẹ́ ilé-iṣẹ́ orin Davido DMW láàrin ọdún 2016 sí ọdún 2021; àkọ́kọ́ orin ìlú mọ̀ọ́ká ẹ̀ ni "Eleko" tí ó kọ ní abẹ́ ilé-iṣẹ́ orin náà.[3] Mayorkun ṣe àfihàn àwọn àkójọ Orin aláàkọ́kọ́ The Mayor of Lagos ní oṣù kọkànlá ọdún 2018. Lẹ́yìn ìgbà tí àjọse àdéhùn tí Mayorkun ní pẹ̀lú Davido Music Worldwide wá sí òpin ní Ọdún 2021. Lẹ́yìn ìgbà yìí ni ó kọ orin titun "Let Me Know" ní abẹ́ ilé-iṣẹ́ orin tí ó ṣẹ̀ kọwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú tí í ṣe ilé-iṣẹ́ Sony Music West Africa.[4] Ó ṣe àfihàn ìkójọ orin ẹ̀ nígbà kejì ìyẹn Back In Office ní oṣù kẹwàá, ọdún 2021, ní abẹ́ ilé-iṣẹ́ Sony Music West Africa .[5]
Remove ads
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads