Mike Bamiloye
Oníṣẹ́-èdè fílìmù Gọ́sìpẹlì àti Akẹ́kọ̀ọ́ fílìmù From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Mike Ayọ̀bámi Bámilóyè ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹ́rin ọdún 1960. Jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, adarí eré, olùgbéré-jáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [3] Ó jẹ́ ajíyìn-rere tí ó ma ń lo eré oníṣẹ́ láti fi jèrè ọkàn àwọn ènìyàn, ó sì tún jẹ́ Olùdásílẹ̀ àti Ààrẹ Mount Zion Faith Ministries[4] àti ti Mount Zion Television. Ó sì tú jẹ́ ọ̀kan lára ìjọ Christ Apostolic Church.
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé rẹ̀
Wọ́n bí Mike ní ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹ́rin ọdún 1960.[5] Ìyá rẹ̀ kú ní nígbà tí ó wà nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rin. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tí ó jẹ́ páítọ̀ Mrs. Felicia Adépọ̀jù Adésànyà ni ó tọ́jú rẹ̀ títí ó fi dàgbà kí ó tó lè mójú tó ara rẹ̀. o lọ si ile-ẹkọ giga ikẹkọ awọn olukọ Divisional College ní ìlú Ìpetu-modù. Ó dá ìjọ Mount Zion ní ọjọ́ Karùún oṣù Kẹrin ọdún 1985. [6] Eré tí ó gbé jáde ni Hell in Conference ni wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ ní National Christian Teachers Conference ní ọdún 1986 ní ìlú Iléṣà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun .[7] Ó ti kópa, darí ati gbé àwọn eré ọlọ́kan-ò-jọkan jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. [8]
Remove ads
Ìgbésí ayé rẹ̀
Ní inú oṣù kẹ́jọ ọdún 1985, ìyàwó rẹ̀ arábìnrin Gloria Bámilóyè gbà láti jẹ́ aya rẹ̀, èyí ni ó sì bẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ìjọ wọn (Mount Zion). Wọ́n bí àwọn ọmọ mẹ́rin (Damilola, Joshua, and Darasimi Mike-Bamiloye).[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
Ẹ tún lè wo
- List of Yoruba people
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads