Muhammadu Buhari
Aare orile-ede Naijiria tele From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Muhammadu Buhari (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ ketàdínlógún, Oṣù Kejìlá Odún 1942 o si ku ni Oṣu Keje ọjọ 13, Ọdun 2025) olóṣèlú tí ó jẹ́ Ààrẹ orílè-èdè Nàíjíríà láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2023.[5][6] Ó lo ṣáà àkọ́kọ́ rẹ̀ láàrin odún 2015 sí 2019 àti kejì láàrin ọdún 2019 sí 2023[7]. Buhari tí fìgbà kan jẹ́ ogágun Méjọ̀ Gẹ́nẹ́rà àti pé ó j̣e olórí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lati 31st Oṣù kejìlá odún 1983 sí Oṣù kẹjó odún 1985, léyìn tí ó fi kúùpù ológun gbàjọba.[8][9]
Remove ads
Igbesi aye tete
A bí Muhammadu Buhari sí ìdílé Fulani ní ọjọ 17 Kejìlá 1942, ní Daura, Ìpínlè Katsina[10], baba rẹ ni Hardo Adamu, ẹni tí ó jẹ́ olori Fulani, orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Zulaihat, ẹni tí ó Hausa.[11][12] Òun ni ọmọ kẹtalelogun bàbá rẹ̀. Ìyá Buhari ni ó tọ dàgbà, bàbá rẹ̀ fi ayé sílè nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rinrin[13].
Ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Ológun
Buhari dara pò mó Nigerian Military Training College (NMTC) ní ọdun 1962, ó jẹ́ omo odun kan dínlógún nígbà náà.[14] Ní oṣù kejì ọdún 1964, a yí orúkọ ilé-ìwé ológun náà padà sí Nigerian Defence Academy (NDA).
Ní àárín 1962 sí 1963, Buhari kó nípa ìmò ogun ní Mons Officer Cadet School ní ìlú Aldershot, England.[15] Ní oṣù kínní ọdún 1963, nígbà tí Buhari jẹ́ ọmọ ọdún ogún, a sọ́ di lieutenanti kejì.
Remove ads
Àwọn Ìtókasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads