Whitney Houston

Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America From Wikipedia, the free encyclopedia

Whitney Houston
Remove ads

Whitney Elizabeth Houston (August 9, 1963 – February 11, 2012) jẹ́ akorin, òṣèré, olóòtú eré, àti ẹlẹ́yinjú-àánú ará Amẹ́ríkà. Arábìnrin yìí tí ìnagijẹ rẹ̀ jẹ́ "Ohùn Náà", jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òṣèré orin gbogbo ìgbà tí ó gbajúgbajà jùlọ, lẹ́yìn tí ó fojú hànde nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìgbajúgbajà. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fojú hànde lórí àtẹ òrin tó gbajúgbajà, àti pé àwọn ìkópa rẹ̀ kópa nínú ìbẹ́níṣòó ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti àṣà tó gbajúgbajà.[1][2] [3]

Quick Facts Ọjọ́ìbí, Aláìsí ...

Houston gbajúgbajà fún ìgbólohùn rẹ̀, ìdáyàtọ̀ rẹ̀, àtí mímú kí ìlò ọ̀nà orin ẹ̀mí láti fi kọ orin tàkasúfèe.[4][5] Ní ọdún 2023, ilé-iṣẹ Rolling Stone ṣe àfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni kejì lórí àtò àwọn olórin olókìkì ìgbàdégbà. Houston ti ta okòólénígba mílíọ̀nù àwo-orin káàkiri àgbáyé, léyìí tó mú un jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tó tà jù lágbàáyé, nínú ìtàn. Ó tún rí òkìkí rẹ̀ nípa ṣíṣe olóòtú àti kíkópa nínú àwọn eré àgbéléwò ajẹmọ́-oríṣiríṣi-àṣà. Ìgbéayé àti iṣẹ́ rẹ̀ ti jẹ ohun àmẹ́nubà fún ìkótànjọ àti ìmẹ́nubà lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.

Houston bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ní New Hope Baptist Church ní Newark, New Jersey, gẹ́gẹ́ bí i ọmọdé, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ń kọrin ní ilé-ìwé rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti farahàn nínú orin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Seventeen, lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣé módẹ́ẹ̀lì ní ọdún 1981. Pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà alága Arista Records, ìyẹn Clive Davis, Houston tẹwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ náà ní ọmọdún mọ́kàndínlógún (19). Àwọn orin àkọ́kọ́ rẹ̀ ni Whitney Houston (1985) àti Whitney (1987), tí ó sì tà gan-an lọdún náà.

Remove ads

Àwọn ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads