Anne Njemanze

Òṣéré orí ìtàgé From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

Anne Njemanze, jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún àwọn ipa rẹ̀ nínu àwọn eré bíi Domitila, Tinsel, Ìrètí àti Colourless.[2][3]

Quick Facts Ọjọ́ìbí, Orílẹ̀-èdè ...

Ọ̀rọ̀ Ayé Rẹ̀

Ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú òṣèré Nollywood Segun Arinze, ṣùgbọ́n àwọn méjèjì ti pínyà.[4] Wọ́n bí ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Renny Morẹ́nikẹ́.[5][6]

Ní Oṣù Kọkànlá Ọdún 2013, ó tún ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Silver Ojieson, ṣùgbọ́n ìgbeyàwọ́ náà kò tún ju oṣù mẹ́jọ lọ tí wọ́n fi kọrawọnsílẹ̀.[7]

Iṣẹ́ Ìṣe Rẹ̀

Ní ọdún 1995, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Rattle Snake. Lẹ́hìn náà ló di ìlúmọ̀ọ́ká pẹ̀lú kíkópa rẹ̀ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Domitilla àti Domitilla II.[8] Lẹ́hìn náà, Ó tún kópa nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ True Confession ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Liz Benson.

Ní ọdún 2012, ó kó ipa ti "Inspector Sankey" nínu eré M-Net aláṣeyọrí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tinsel .[9]

Àwọn Eré Rẹ̀

More information Year, Film ...

Àwọn ìtọ́kasí

Ìjápọ Síta

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads