Eve Esin
oníṣeré àwòrán láti ìbílè Naijiria From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Eve Esin jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ ti City People Entertainment Awards fún ẹ̀ka ti Òṣèrébìnrin tó ní ìlérí jùlọ ni Nàìjíríà ní ọdún 2015, àmì-ẹ̀yẹ ti AMAA fún amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ àti àmì-ẹ̀yẹ AMVCA fún ti òṣèrébìnrin tó dára jùlọ nínu eré ìtàgé.[1][2][3]
Remove ads
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
A bí Esin ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibọm, ní ìjọba agbègbè Oron, gúúsù Nàìjíríà. Esin parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ìlú abínibí rẹ̀ ní Akwa Ibom.Lẹ́hìn èyí, ó tẹ̀síwájú láti ka ìwé mẹ́wàá ní Immaculate Conception Secondary School tí ó wà ní agbègbè Itak-Ikono, Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom níbi tí ó ti gba Ìwé-ẹ̀rí fún ìparí ẹ̀kọ́ mẹ́wàá rẹ̀. Lẹ́hìn náà, Esin lọ sí Yunifásitì ìlú Calabar ní Ìpínlẹ̀ Cross River níbití ó ti gba oyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ eré ìtàgé.[4][5][6]
Remove ads
Iṣ́ẹ ìṣe rẹ̀
Ṣáaj́u kí Esin tó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà tí a mọ̀ ní Nollywood ní ọdún 2008, ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ kí ó tó padà wá fi òpin sí ṣíṣẹ iṣẹ̀ náà láti lè gbájúmọ́ iṣẹ́ òṣèré. Esin darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù tí Nàìjíríà (Nollywood) ní ọdún 2008 lẹ́yìn ṣíṣe àyẹ̀wò láti kópa nínu fíìmù kan níbití ó ti ṣàṣeyọrí tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkópa nínu fíìmù náà. Esin ṣe àkọ́kọ́ dídaŕi fíìmù pẹ̀lú dídarí fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Spirit. Gẹ́gẹ́bí ilé-iṣẹ́ oníròyìn The Tribune ti ṣe sọ di mímọ̀, Esin ti ní ìfihàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún nínu fíìmù.[7]
Remove ads
Àwọn ìyẹ́sí rẹ̀
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
- Blue (2019)
- Pains Of Life (2017)
- Girls Are Not Smiling (2017)
- Treasure (2017)
- The Storm (2016)
- Marry Who You Love (2016)
- Oshimiri (2015)
- Idemili (2014)
- Brothers War (2013)
- Brave Mind (2012)
- Deep Water (2012)
- Hand Of Fate (2012)
- Sins Of The Past (2012)
- The Enemy I See (2012)
- Gallant Babes (2011)
- Thanks For Coming (2011)
- Mad Sex (2010)
- Royal War (2010)
- Indecent Desire (2005)
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads