Ìpínlẹ̀ Imo
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Ìpínlẹ̀ Imo (Igbo: Ȯra Imo) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè gúúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí àríwá pẹ̀lú Ìpínlẹ Anambra, Ìpínlẹ̀ Rivers sí ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù, àti Ìpínlẹ̀ Abia sí ìlà-oòrùn.[3] Ó mú orukọ rẹ látara odò Imo tí ó ń sàn jákèjádò ààlà ìlà-oòrùn. Olú-ìlú ìpínlẹ̀ náà ni Owerri tí orúkọ ìnagigẹ rẹ̀ ń jẹ́ "ọkàn ìlà-oòrùn" "Eastern Heartland."[4]
Laaarin àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Imo jẹ́ ìpínlẹ̀ kẹta tí ó kéré jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù-márùn-únlé-ní-ọgọ́rùn-lọ́nàerínwó gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[5]
Lóde-òní ìpínlẹ̀ Imo ní àwọn olùgbé láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà, pàápàá àwọn ará Igbo pẹ̀lú èdè Igbo tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ ní ìfẹ̀gbẹ̀kẹg̀bẹ́ pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì jákèjádò ìpínlẹ̀ náà. Ṣáájú àkókò ìmúnisìn, ohun tí ó ń jẹ́ Ìpínlẹ̀ Imo ní báyìí jẹ́ apákan ti ìjọba àtijọ́ ti Nri àti Aro Confederacy nígbà míì ṣáájú kí wọ́n tó ṣẹ́gun lẹ́yìn-òrẹyìn ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdùn 1900 nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun ìlu Gẹ̀ẹ́sì ní Ogun Anglo-Aro. Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dá agbègbè náà sí Gúúsù Nàìjíríà lábẹ́ àbẹ̀ àwọn aláwọfunfu ni èyí tí ó wá dà Nàìjíríà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pọ̀ ní ọdún 1914; lẹ́yìn ìdàpọ̀ náà, Imo di àáríngbùngbùn fún ìdẹ́kun-ìmúnisìn nígbà Ogun àwọn Obìnrin.[6]
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Remove ads
Itokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads