Mali

From Wikipedia, the free encyclopedia

Mali
Remove ads

Mali, fun tonibise bi Olominira ile Mali (Faransé: République du Mali), je orile-ede tileyika ni Apaiwoorun Afrika. Mali ni bode mo Algeria ni ariwa, Nijer ni ilaorun, Burkina Faso ati Côte d'Ivoire ni guusu, Guinea ni guusu-iwoorun, ati Senegal ati Mauritania ni iwoorun. Itobi re fi die ju 1,240,000 km² lo pelu iye awon eniyan to ju egbegberun 14 lo. Oluilu re wa ni Bamako.

Quick Facts Olómìnira ilẹ̀ Málì Republic of Mali République du Mali, Olùìlú àti ìlú tótóbijùlọ ...

Mali ni agbegbe mejo be sini awon bode re ni ariwa sun de arin Sahara, nigbati agbegbe apaguusu, nibi ti opolopo eniyan ngbe, ni awon odo Niger ati Sénégal. Ise agbe ati ise apeja ni won se ju nibe. Awon ohun alumoni Mali ni wura, uraniomu, ati iyo. Mali je ikan ninu awon orile-ede to je talaka julo mi agbaye.

Present-day Mali oni fi igba kan wa ni apa awon ile obaluaye meta ti Iwoorun Afrika to n dari idunadura kiri Sahara: Ile Obaluaye Ghana, ile Obaluaye Mali (nibiti orile-ede Mali ti gba oruko re), ati Ile Obaluaye Songhai. Ni opin awon odun 1800, Mali bo sowo awon ara Fransi, o di apa Sudan Fransi. Mali gba ilominira ni 1959 lapapo mo Senegal, gege bi Ile Apapo Mali. Leyin odun kan, Ile Apapo Mali di orile-ede alominira ile Mali. Leyin igba pipe ijoba egbe oloselu-kan, ifipagbajoba ni 1991 mu ilana-ibagbepo titun jade ati idasile Mali gege bi orile-ede toseluaralu egbe oloselu-pupo.


Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads