Àwọn Ogun Napoleon

From Wikipedia, the free encyclopedia

Àwọn Ogun Napoleon
Remove ads

OGUN NAPOLEON

Quick facts Awon Ogun Napoleon, Date ...

Ìjàgbara tí a ń pe ní revolution tí ó ṣẹlẹ̀ ní France jẹ́ kí Fance ní ọ̀tá púpọ̀ ní ìlú Òyìnbó. Èyí ni ó sì fa ogun tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin 1792 sí 1815 tí ó fẹ́rẹ̀ máa dáwó dúró.

Ní àsìkò ogun yìí, ilẹ̀ Faransé ní Ọ̀gágun kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Napoleon Bonaparte. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni Napoleon ṣẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun wọ̀nyí, ó sọ ara rẹ̀ di emperor ní 1804. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti di olórí ilẹ̀ Faransé tán ó tún fẹ́ di olórí gbogbo ìlú Òyìnbó. Nítorí ìdí èyí, gbogbo ìlú Òyìnbó ni ó wá gbógun tì í kí àbá rẹ̀ yìí má baà lè ṣẹ.

Àwọn ìlú tó ń bá ilẹ̀ Faransé jà nígbà náà ni Austria, Prussia, Russia, Britain àti Spain. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé pọ̀ gan-an ni. Wọ́n ṣẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun. Àwọ́n eléyìí tí ó ṣe pàtàkì jù ni ogun Marengo àti Hohenlinden ní 1800 ti Austerlitz ní 1805 àti ti Jena ní 1806. Ìṣẹ́gun yìí fún Napoleon ní agbara láti máa darí ilẹ̀ ìlú Òyìnbó.

Ṣùgbọ́n sá, àwọn ológun ojú omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lágbára gan-an ni. Ọ̀gá wọn ni Lord Nelson. Wọ́n ṣẹ́gun ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé ní ogun Nile ní 1798. Èyí ni kò jẹ́ kí ilẹ̀ Faranse rí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbà.

Inú bí Napoleon, kò jẹ́ kí àwọn ọja ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọjá sí àwọn ilẹ̀ ìlú Òyìnbó mìíràn mọ́. Àìrí ọjà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí dá wàhálà sílẹ̀ fún àwọn ilẹ̀ yòókù. Spain yarí. Ó gbógun ti Napoleon. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ ran Spain lọ́wọ́. Ẹni tí ó ṣaájú ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ ni Arthur Wellesley tí ó padà wá ń jẹ́ Duke of Wellington. Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìja kan. Ó ṣe, Russia dara pọ̀ mọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Spain. Napoleon ṣígun lọ sí Russia ṣùgbọ́n gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ ni ó kí sí ọ̀hún. Torí gbogbo ìṣẹ̀gun wọ̀nyí, Bsritain, Prussia, Sweden, Russia àti Astria para pọ̀ láti bá ilẹ̀ Faranse jà. Wọ́n ṣẹ́gun. Wọ́n wọ Paris ní 1814. Ní 1815, wọ́n lé Napoleon lọ sí Elba. Ó sá àsálà ó sì wá bá ọmọ ogun Britain àti Prussia jà ni Waterloo. Wọ́n ṣẹ́gun Napoleon wọ́n wá lé e lọ sí St Helena.


Remove ads

Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads