Olukayode Ariwoola

From Wikipedia, the free encyclopedia

Olukayode Ariwoola
Remove ads

Adájọ́-àgbà, Olúkáyọ̀dé Ariwoọlá CJN [1],GCON[2]ni wọ́n bí lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1958 (22 August 1958) jẹ́ Adájọ́-àgbà-yányán ti Orilẹ̀-èdè Nigeria tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹfà ọdún 2022. Wọ́n yàn án sípò Adájọ́-àgbà-yányán lẹ́yìn tí Adájọ́-àgbà, Tanko Mohammad fìwé kọpòsílẹ̀̀[3] [4] [5]. Kí wọ́n tó yàn án, ó jẹ́ Adájọ́-àgbà ní ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣíwájú àkókò náà, ó ti jẹ́ adájọ́-àgbà nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.[6][7]

Quick facts Olúkáyọ̀dé Ariwoọlá, Acting Chief Justice of Nigeria ...
Remove ads

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀

Wọ́n bí Ariwoọlá ní ìlú Ìsẹ́yìnÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ alákòósoọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Local Authority Demonstration School,tí ó wà ní agbègbè Olúwọlé ní ìlú ìsẹ́yìn. Ó tún sílé ẹ̀kọ́ Muslim Modern School láarín ọdún 1968 sí 1969 ní ìlú ìsẹ́yìn tí ó sì tún dẹ̀yìn lọ sílé ẹ̀kọ́ girama Ansar-Ud-Deen High School ní ìlú ṣakí ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kan náà.[8]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin

Ariwoọlá kàwé gboyè nílé ẹ̀kọ́ fáfitì ti Obafemi Awolowo University, ní ìlú Ilé-Ifẹ̀Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí ó sì Gb'oyè Bachelor's degree in Law (LLB). Ó di ìkan nínú ọmọ ẹgbẹ́ Nigerian bar gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò, ó sì wọ ilé-ẹjọ́ ti Supreme Court of Nigeria gẹ́gẹ́ bí olùlajà ati agbẹjọ́rò ní inú oṣù keje ọdún 1981. Ó ṣe ìsìnrú-ìlú rẹ̀ (NYSC) nílé iṣẹ́ Ministary of justice tí ó wà ní Ìlú Àkúrẹ́Ìpínlẹ̀ Òndó tí ó sì tún di òṣìṣẹ́ amòfin nílé iṣẹ́ Ministary of Justice ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ títí di ọdún 1988 tí ó fi fiṣẹ́ ìjọba sílẹ̀ tí ó sì dara pọ̀ mọ́bilé-iṣẹ́ amòfin aládàáni. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò lábẹ́ ìṣàkóso adájọ́ Ladoṣù Ládàpọ̀(SAN) láti oṣù Kẹwàá ọdún 1988 sí oṣù keje ọdún 1989. Lẹ́yìn tí ó kúrò níbiẹ̀ ni ó dá Ilé-iṣẹ́ amòfin tìrẹ sílẹ̀ tí ó pe ní Olukayode Ariwoola & Co, ní inú oṣù Kẹwàá ọdún 1989. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí adájọ́ sílé ẹjọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìkọkànlá ọdún 1992. Òun ni Alága àgbà fún Ìgbìmọ̀ Adarí ti Phonex Motors Ltd tí ó jẹ́ ìkan lára ẹ̀ka Oòdúà Investment. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ní ìlú Ìbàdàn lẹ́yìn tí wọ́n gbe kúrò ní ìlú Ṣakí, tí ó sì jẹ Alàgbà ìgbìmọ̀ fún ẹ̀ka ìgbàẹ́jọ́ ìdigun-jalè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrín ọdún 1993 sí ọdún 1996. Ariwoọlá ni ó tún ti ṣiṣẹ́ ní ilé-ẹjọ́ ti àgbà gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún ìgbẹ́jó kòtẹ́mi-lọ́rùn ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná , Ìpínlẹ̀ Enugu ati Ìpínlẹ̀ Èkó. Lọ́wọ́ lọ́wọ́ yí, òun ni Adájọ́ Àgbà (CJN) fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[9][10]

Remove ads

Ọmọ ẹgbẹ́

Ọlá Orílẹ̀-èdè

Ni oṣù kẹ́wàá ọdún 2022, Grand Commander of the Order of Niger (GCON), ọlá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a fún Ariwoola nípasẹ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari.[11]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads