CJN

From Wikipedia, the free encyclopedia

Remove ads

chief justice of Nigeria tàbí CJN ni ó jẹ́ ipò adarí àgbà fún ẹ̀ka ètò ìdájọ nínú ìṣèjọba orílẹ̀-èdè Nàìj́íríà. Ẹni tí ó bá wà ní orí ipò yì ni ó ma ń gb'ẹ́jọ́ orílẹ̀-èdè nílé ẹjọ́ àgbà tí a mọ̀ sí Supreme Court of Nigeria àti National Judicial Council.[1] Ilé-ẹjọ́ àgbà The Supreme Court of Nigeria ni ó jẹ́ ilé-ẹjọ́ tí o ga jùlọ ní orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìpinnu àti ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ yí ni abẹ́ gé.[2] Adájọ́ àgbà tí ò wà lórì àpèrè ni órílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò tí a ń kọ àyọkà yí ni Kudirat Kekere-Ekun, ẹni tí wọ́n yàn sípò náà ní ọjọ́kejìlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2024.[3] Ṣáájú kì ó tó di adájọ́ àgbà, wọ́n kọ́kọ́ yàn án sípò adelé adájọ́ àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn tí adájọ́ àgbà tẹ́lẹ̀rí Olukayode Ariwoola fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ó ma ń yan ẹni tí yóò dipò yí mú lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ bá fun ní àbá nípa irúfẹ́ ẹni tì ipò náà tọ́sí, lẹ́yìn èyí ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà yóò buwọ́ lù ẹni náà kí ó lè di adájọ́ àgbà fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4] Adájọ́ àgbà ni ó lẹ́tọ̀ọ́ láti dipò náà mú ní ìbámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Adájọ́ àgbà náà ní àǹfání láti dipò náà mù tìtí ikú yóò fi yọ ọ́ níṣẹ́, tàbí kí ó fipò náà sílẹ̀ nígbà tí ọjọ́-orí rẹ̀ bá ti pé àádọ́rin ọdún tàbì kì àwọn ilè-aṣòfin àgbà yọ ọ́ nípò pẹ̀lú ìbò láàrìn ara wọn.[5]

Quick facts Chief Justice the Supreme Court of Nigeria, Style ...
Remove ads

Àtòjọ àwọn adájọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà

[6]

More information Chief Justice, Term ...
Remove ads

Àtòjọ àwọn adájọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ẹkù-jẹjkùn

Láti ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà (1863–1929)
  • Benjamin Way (?–1866)
  • John Carr (1866–?) (West African Settlements Supreme Court)
  • George French (1867–1874)
  • James Marshall (1874–1886)
  • Sir John Salman Smith (1886–1895)
  • Sir Thomas Crossley Rayner (1895–1902)
  • Sir William Nicholl (1902–1908)
Láti gúasù Nàìjíríà
  • Alastair Davidson (1900–1901)
  • Henry Cowper Gollan (1901–1905)
  • Sir M R Menendez (1905–1908)
  • Sir Edwin Speed (1908–1913)
Láti ìlà oòrun Nàìjíríà
  • Henry Green Kelly (1900–1902)
  • Willoughby Osborne (1906–1913)
Remove ads

Àwọn ìtọ́kasí

Awon ìjásóde

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads