Segun Awolowo

From Wikipedia, the free encyclopedia

Segun Awolowo
Remove ads

Olúṣẹ́gun Awólọ́wọ̀ Jr. (wọ́n bí i ní 27 September 1963), jẹ́ agbẹjọ́rò ọmọ nàìjíríà, ó jẹ́ Alákòóso Àgbà fún Nigerian Export Promotion Council, láti ọdún 2013 dé ọdún 2021 .[1][2]. Ó jẹ́ ọmọ-ọmọ àgbà Olóṣèlù Nàìjíríà nnì, Olóyè Obafemi Awolowo .[3] Ní oṣù keje ọdún 2021, wọ́n panupọ̀ dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bí i ààrẹ àwọn àjọ tóń ṣe ìgbélárugẹ fún òwò ní orílẹ̀ èdè yìí (TPOs) láti ara ECOWAS member States.[4][5]

Quick Facts Segun Awolowo LLB, Ààrẹ National Trade Promotion Organisation ...
Remove ads

Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé Rẹ̀

Wọ́n bí Awólọ́wọ̀ ní 27 September 1963, bàbá rẹ̀ (Ṣẹ́gun Awólọ́wọ̀ Sr.) kú ní 1965 ní ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n láti ara ìjàm̀bá ọkọ̀ ní òpópó márosẹ̀ ìbàdàn sí Èkó àtijọ́ [6] . Ẹ̀yìn oṣù méjì tí bàbá rẹ̀ kú ni wọ́n bí i [7], ọ̀dọ̀ Ẹ̀gbọ́n Bàbá rẹ̀ ni ó gbé ka ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Abilékọ Tola Oyediran (nee Awolowo) àti ọkọ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayode Oyediran. Kí ó tó dìgbà náà, ó gbé lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ àti àwọn tòun ti àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀.[8]

Remove ads

Ẹ̀kọ́

Awólọ́wọ̀ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Mayhill Convent School tòun ti Dolapo Osinbajo, ìyàwó igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo,lábẹ̀ àmójútó Ọ̀jọ̀gbọ́n àti Mrs Oyediran. láti ibẹ̀ , ó tẹ̀ síwájú lọ sí Igbobi College, Yaba, Ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State) fún ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì tí ó sì parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírí rẹ̀ ní Government College, Ibadan. Lọ́gán tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì rẹ̀ ni ó tẹ̀síwájú lọ sí Ogun State University (now Olabisi Onabanjo University), Ago Iwoye tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde pẹ̀lú oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ LLB. [9]

Remove ads

Iṣẹ́

Awolowo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ amòfin Abayomi Sogbesan & Co. àti ilé iṣẹ́ amòfin ti GOK Ajayi & Co. lẹ́yìn ìgbà tí ó wọ àwùjọ àwọn agbẹjọ́rò ní oṣù kejìlá ọdún 1989. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba President Olusegun Obasanjo's gẹ́gẹ́ bí Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ àbàláyé, ètò àti ọ̀rọ̀ òfin. [10]

Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba Umaru Musa Yar'Adua gẹ́gẹ́ bí Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì tí ó sì ṣiṣẹ́ ní agbègbè ìjọba Àpapọ̀ gẹ́gẹ́ bí i akọ̀wé fún ètò ìdàgbàsókè àwùjọ àti Akọ̀wé fún ètò ìrìnà ọkọ̀ láti 2007 di 2011. Ó padà sí ìdí iṣẹ́ òfin rẹ̀ lẹ́yìn ètò ìdìbò ọdún 2011 títí di 2013 tí Ààrẹ t Goodluck Jonathan yàn-án sí ipò Alákòóso àgbà fún ilé iṣẹ́ Nigerian Export Promotion Council[11] tí iṣẹ́ rẹ̀ sì tẹnubodò ní ọdún 2017, oṣù kọkànlá ṣùgbọ́n Ààrẹ Muhammadu Buhari tún tún-un yàn sí ipò yìí kan náà ní Oṣù kejì 2018 fún sáà ọdún mẹ́rin mìíràn.[12][13]

Ìgbésí Ayé

Awólọ́wọ̀ ní ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ọmọbìnrin rẹ̀ Ṣeun jẹ́ ọlọ́rọ̀ ìyànjú tí ó sì ń darí ilé iṣẹ́ kan tí kìí ṣe ti ìjọba tí à ń pè ní Teach-A-Girl Nigeria. Èyí tí ó gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbìnrin ní Nigeria. Òun yìí kan náà ni Òlùdásílẹ̀ Leads Africa àti 3D Living Moments.[14]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Remove ads