Ìran Yorùbá
ẹya ti Iwọ-oorun Afirika From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Ìran Yorùbá, àwọn ọmọ Yorùbá tàbí Ọmọ káàárọ̀-oòjíire, jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Áfíríkà, ní apá Ìwọ̀-Oòrùn rẹ̀, tí wọ́n ń gbé apá kan ní ilẹ̀ Nàìjíríà, Bẹ̀nẹ̀, àti Togo, wọ́n sì ń pè gbogbo agbègbè yìí ní Ilẹ̀ Yorùbá.[23] Ẹ lè ri púpọ̀ nínú wọ́n ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Kwara, ìpínlẹ̀ Kogí, ìpínlẹ̀ Ògùn, Ìpínlẹ̀ Oǹdó, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ẹ tún le rí wọ́n ní ìpínlẹ̀ to wa nínú orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin (Dahomey), ní orílẹ̀-èdè Sàró (Sierra Leone), àti ní àwọn orílẹ̀-èdè miiran bíi Togo, Brazil, Cuba, Haiti, Amẹ́ríkà ati Venezuela. Àwọn Yorùbá wà l’árá àwọn to tóbí ju ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó le jẹ́ pe àwọn ló pọ̀ jù, abí kí wọ́n jẹ́ ìkejì, tàbí ẹ̀yà kẹta tó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[24][25][26][27]

Àwọn Yorùbá jẹ́ àwọn ènìyàn kan ti èdè wón pín sí orísirísi. Diẹ̀ lára àwọn ìpínsísọ̀rí àwọn èdè wọn ni a ti ri: "Èkìtì"; "Èkó"; "Ìjèbú"; "Ìjẹ̀ṣhà"; "Ìkálẹ̀"; "Ọ̀yọ́"; "Ẹ̀gbá" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìpínsísọ̀rí yí ni a ń pe ní ẹ̀ka èdè tàbí èdè àdúgbò. Àwọn ọmọ Yorùbá je ẹ̀yà kan tí wọ́n fẹ́ràn láti máà se aájò àti àlejò àwọn ẹlẹ́yà mìíràn, wọ́n sì ma ń nífẹ̀ẹ́ sí ọmọ'làkejì.

Remove ads
Ìpínlẹ̀
Ní ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn Yorùbá pín ààlà ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà mìíràn, bíi; Yoruboid Itsekiri tó wà ní apá Gúúsù-ìlà-oòrùn, Niger Delta ní apá Gúúsù Ìwọ̀-oòrùn , Bariba ní apá Àríwá-Ìwọ̀-oòrùn ní ilẹ̀ Bẹ̀nẹ̀ àti Nàìjíríà, àwọn Nupe ní apá Àríwá, àti àwọn Ebira ní apá Àríwá-Ìlà-oòrùn, ní Ààrin Gbùngbùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Sí apá Ìlà-oòrùn wọn nih àwọn ẹ̀yà bíi Edo, Esan, àti Afemai wà. Sí apá Àríwá-Ìwọ̀-oòrùn wọn ní àwọn ẹ̀yà tó jẹ mọ́ Ìgalà wà, lágbègbè Niger River. Sí apá Gúúsù wọn ni àwọn ẹ̀yà bíi Gbe, Mahi, Fon, Ewe tó ń pín ààlà ilẹ̀ pẹ̀lú Benin àti Togo. Ní Ìwọ̀-oòrùn, àwọn èyà tó ń sọ èdè Kwa bíi Akebu àti Kposo ti Togo ni wọ́n yí àwọn Yorùbá ká, bẹ́ẹ̀ sì ni a ní àwọn tó ń sọ èdè Kwa bíi Anii, àti àwọn tó ń sọ èdè Gur bíi Kabiye, Yom-Lokpa àti Tem ti Togo[28] ní apá Àríwá-Ìwọ̀-oòrùn.
Àwọn ọmọ Yorùbá tun wà ní orílẹ̀-èdè West Africa míì bíi Ghana[29][30][31], Benin,[29] Côte d'Ivoire,[32] àti Sierra Leone.[33]
Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ilẹ̀ Áfíríkà, ìtànkálẹ̀ àwọn Yorùbá pín sí ọ̀nà méjì pàtàkì, àkọ́kọ́ ni àwọn Yorùbá tí wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ tuntun gẹ́gẹ́ bí ẹrú láàárín sẹ́ńtúrì kẹrìndínlógún (16th century) sí sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún (19th century), sí àwọn ilẹ̀ Caribbean (pàápàá jùlọ Cuba) àti Brazil.
Ẹ̀kejì sì ni àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí kó lọ sí United Kingdom àti United States ní àkókò tí ayipada ń dé bá ètò ọrọ̀-ajé àti òṣèlú ilẹ̀ náà láti ọdún 1960 títí di àkókò yìí.[34]
Remove ads
Èdè

Ìtàn àtẹnudénu lásán ni àṣà Yorùbá jẹ́ nígbà kan, ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá ni èdè náà sì jẹ́ abínibí fún. Ní ọdún 2010, àwọn tó ń sọ èdè náà tó ọgbọ̀n mílíọ́ọ̀nù[39]. Wọ́n pín èdè Yorùbá pọ̀ mọ́ àwọn èdè bí i Edekiri, Igala tọ́ parapọ̀ di àwọn èdè Yoruboid ní agbègbè Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà.
Èdè Igala àti Yorùbá ní ìbáṣepọ̀ pàtàkì nípa ìtàn àti àṣà. Èdà ẹ̀yà méjèèjì yìí ní àwọn ìjọra kọ̀ọ̀kan, tó bẹ́ẹ̀ tí Forde (1951) àti Westermann àti Bryan (1952) fi ka èdè Igala sí abẹ́ àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá.
A lè pín àwọn ẹ̀ka-èdè tó wà lábẹ́ èdè Yoruboid sí ọ̀nà mẹ́ta: Northwest, Central, àti Southeast.[40] Àwọn ẹ̀ka-èdẹ̀ tó wà ní North-West Yoruba (ní apá Gúúsù mọ́ Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Yorùbá) ń fi àrà tuntun èdè náà hàn, pẹ̀lú ìfilélè pé Southeast àti Central Yoruba ní àwọn ìlú àtijọ́, ti wọ́n sì lè ṣí lọ sí àwọn ìlú mìíràn.[41]
Remove ads
Ona asopo ti orisirisi dialects ti èdè Yoruba:
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:A_short_oral_history_of_Egba_in_Egba_Language_by_its_native_speaker.webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_Oral_history_of_Okeho_in_Onko_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_Oral_history_of_Saki_in_Saki_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Iwo_in_Iwo_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Ijan_Ekiti_in_Ijan_Ekiti_Language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Ile_Ife_in_Ile-Ife_language_by_a_native_speaker.webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Ilesha_in_Ijesha_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:A_short_oral_history_of_Irun_in_Irun_Akoko_dialect_by_native_speaker.webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Owo_in_Owo_language_by_a_native_speaker.webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Idanre_in_Idanre_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Ijebu_in_Ijebu_language_by_a_native_speaker.webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:Short_oral_history_of_Ikale_in_Ikale_language_by_a_native_speaker_(non-subtitled).webm
- https://en.wikipedia.org/wiki/File:A_short_oral_history_of_Isua_in_Ifira_dialect_by_a_native_speaker.webm
Ohun pataki ni asa ati èdè Yoruba
Ni asa ati èdè Yoruba, òwó se pataki gidigan. Ni asa wa, ti e ba fe ki awon agba tabi awon èniyàn ti o tobi ni odun ju iwo. O nilo lati dobale, e ko le so "bowani" e ma se be o! E nilo lati dọbalẹ. Ni asa wa ati ni èdè wa, òwó se pataki gidigan, ti èniyàn tobi ni odun ju iwo e nilo lati fikun "e" siwaju ohun ti e fe so. "E kaaro," "E pele," "E kúuṣẹ́," sùgbón ti e ba ba àwọn èniyàn soro ti o ni odun kekere ju iwo tabi ti won ni odun ti je kanna pèlú iwo, e ma lo "e" e le n so "kaaro," "pele," ati "kúuṣẹ́."
Remove ads
Se o je otito pé edè Yoruba n fi ku?


Bee ni, o je otito pé ede Yoruba n fi ku? Kini ede fun be? Idi fun iku ede Yoruba je pé awon obi, won ko fe ko awon omodé re ede Yoruba. Opolopo èniyàn ro pé ede Yoruba ko se pataki. Won ro pé ede Yoruba je fun awon otoshi, awon talaka ati awon èniyàn ti ko ni eto-eko (awon láìlẹ́kọ̀ọ́). Sùgbon, o ko je otito, Yoruba ko je fun awon èniyàn ti o ni eto-eko, Yoruba je fun gbogbo èniyàn Yoruba. Awa nilo lati yipada ero inu wa. O ko dara nigba awa n so pé ede Yoruba ko se pataki tabi o je fun awon lailekoo. Opolopo èniyàn bere lati ikorira ede abinibi won dabi Yoruba, Igbo, ati awon miiran. Awa nilo lati mu Yoruba pelu wa, ki i se fi Yoruba ni idoti. Awon Germans won n so German ati inu won dun gidigidi nitori won n so German, awon Chinese won n so Chinese ati inu won dun gidigidi nitori won n so Chinese, awon Russians, won n so Russian ati inu won dun gidigidi nitori won n so Russian sùgbon awon Yoruba, won ko n so Yoruba, ati inu won ko dara nitori won n so Yoruba, ni otito, won n ko fe so Yoruba. Akoko ti dé, awa nilo lati yipada ero inu wa, ko dara. Awon omodé ni Canda, Amerika, China, Jermani, ati awon Dutch, omodé won, won n so ede ti obi won, sùgbon awon omodé wa, won ko so ede wa.
Èdè Yoruba ni ogbon ati orisirisi owe, awa nilo lati soji ede Yoruba, ti awa ko soji ede Yoruba, o ma fi ku patapata, ati awa ko le soji ede Yoruba. Akoko ti de, awa nilo lati se kankan, sugbon o ma fi ku patapata.
Remove ads
Àwọn Ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads